Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 115:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

11. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

12. OLUWA ranti wa, yóo bukun wa,yóo bukun ilé Israẹli,yóo bukun ìdílé Aaroni.

13. Yóo bukun àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,ati àwọn ọlọ́lá ati àwọn mẹ̀kúnnù.

14. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ máa bí sí i,àtẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín.

15. Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín!

16. OLUWA ló ni ọ̀run,ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan.

17. Àwọn òkú kò lè yin OLUWA,àní àwọn tí wọ́n ti dákẹ́ ninu ibojì.

18. Ṣugbọn àwa yóo máa yin OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ, ati títí laelae.Ẹ máa yin OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 115