Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 115:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa,orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ.

2. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi bèèrè pé,níbo ni Ọlọrun wa wà?

3. Ọlọrun wa wà ní ọ̀run,ó ń ṣe ohun tí ó wù ú.

4. Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn,iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.

5. Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran.

6. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn.

7. Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 115