Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 113:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA.

2. Kí á yin orúkọ OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae.

3. Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,kí á máa yin orúkọ OLUWA.

4. OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ,ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ.

5. Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa,tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run,

6. ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀láti wo ọ̀run ati ayé?

7. Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀,ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú,

8. láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè,àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀.

9. Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ,ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn.Ẹ máa yin OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 113