Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 11:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀,ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run;OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan,ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò.

5. OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò,ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá.

6. Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú;ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn.

7. Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo;àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 11