Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 109:5-22 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi,ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.

6. Yan eniyan burúkú tì í,jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́.

7. Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀,jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi;kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn.

8. Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú,kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà.

9. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba,kí aya rẹ̀ di opó.

10. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká,kí wọn máa ṣagbe kiri;kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé.

11. Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀,kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀.

12. Kí ó má bá aláàánú pàdé,kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba.

13. Kí ìran rẹ̀ run,kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀.

14. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀,kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́.

15. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo,kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé.

16. Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú,ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní,ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n.

17. Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè;nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí;inú rẹ̀ kò dùn sí ìre,nítorí náà kí ìre jìnnà sí i.

18. Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù,kí èpè mù ún bí omi,kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn.

19. Kí èpè di aṣọ ìbora fún un,ati ọ̀já ìgbànú.

20. Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi,àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi!

21. Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà minítorí orúkọ rẹ, gbà mí!Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀.

22. Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 109