Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 109:18-31 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù,kí èpè mù ún bí omi,kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn.

19. Kí èpè di aṣọ ìbora fún un,ati ọ̀já ìgbànú.

20. Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi,àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi!

21. Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà minítorí orúkọ rẹ, gbà mí!Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀.

22. Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ.

23. Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́,a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú.

24. Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,mo rù kan egungun.

25. Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi,wọ́n ń wò mí ní àwòmirí.

26. Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi,gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

27. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí,kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é.

28. Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre.Kí ojú ti àwọn alátakò mi,kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn.

29. Kí ìtìjú bo àwọn ọ̀tá mi bi aṣọ,àní, kí wọn gbé ìtìjú wọ̀ bí ẹ̀wù.

30. N óo máa fi ẹnu mi yin OLUWA gidigidi,àní, n óo máa yìn ín ní àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan.

31. Nítorí pé ó dúró ti aláìníláti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ó dájọ́ ikú fún un.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 109