Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 107:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde,lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

8. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan.

9. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn,ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.

10. Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,

11. nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun,wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo.

12. Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn,wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́.

13. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

14. Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn.

15. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

16. Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá.

17. Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 107