Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 107:35-43 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi.

36. Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé.

37. Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,wọ́n sì kórè lọpọlọpọ.

38. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.

39. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,

40. ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,níbi tí kò sí ọ̀nà.

41. Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú,ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran.

42. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

43. Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi;kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 107