Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 107:32-40 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan,kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà.

33. Ó sọ odò di aṣálẹ̀,ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ,

34. ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀,nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

35. Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi.

36. Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé.

37. Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,wọ́n sì kórè lọpọlọpọ.

38. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.

39. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,

40. ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,níbi tí kò sí ọ̀nà.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 107