Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 107:19-26 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

20. Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá,ó tún kó wọn yọ ninu ìparun.

21. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

22. Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́,kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀.

23. Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi,wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,

24. wọ́n rí ìṣe OLUWA,àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú.

25. Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà,tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè.

26. Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro,wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú,jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 107