Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 107:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2. Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀,àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú,

3. tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì,láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn,láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù.

4. Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀,wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

5. Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n,ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú.

6. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn.

7. Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde,lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

8. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 107