Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 106:34-47 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run,gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn,

35. ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.

36. Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn,èyí sì fa ìpalára fún wọn.

37. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa.

38. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin,ati ti àwọn ọmọbinrin wọn,tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani;wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́.

39. Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè.

40. Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀.

41. Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́,títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí.

42. Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn.

43. Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀,ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i,OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

44. Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn,nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn.

45. Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá,ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

46. Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn.

47. Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa,kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 106