Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 106:18-35 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Iná sọ láàrin wọn,ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.

19. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.

20. Wọ́n gbé ògo Ọlọrunfún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.

21. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,

22. ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa.

23. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.

24. Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.

25. Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.

26. Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọnpé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,

27. ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiriàwọn orílẹ̀-èdè.

28. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.

29. Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.

30. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.

31. A sì kà á kún òdodo fún un,láti ìrandíran títí lae.

32. Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba,wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose,

33. nítorí wọ́n mú Mose bínú,ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.

34. Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run,gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn,

35. ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 106