Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 104:29-35 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Bí o bá fojú pamọ́,ẹ̀rù á bà wọ́n,bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú,wọn á sì pada di erùpẹ̀.

30. Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde,wọ́n di ẹ̀dá alààyè,o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun.

31. Kí ògo OLUWA máa wà títí lae,kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀.

32. Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì,tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín.

33. N óo kọrin ìyìn sí OLUWAníwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi,níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ.

34. Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninunítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA.

35. Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé,kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi!Yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 104