Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 103:16-22 BIBELI MIMỌ (BM)

16. ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,á rẹ̀ dànù,ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.

17. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.

18. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.

19. OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,ó sì jọba lórí ohun gbogbo.

20. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

21. Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

22. Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀.Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 103