Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 103:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.

15. Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;

16. ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,á rẹ̀ dànù,ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.

17. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.

18. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.

19. OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,ó sì jọba lórí ohun gbogbo.

20. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

21. Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 103