Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 103:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

2. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

3. ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn;

4. ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.

5. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 103