Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 102:8-25 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè.

9. Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,mo sì ń mu omijé mọ́ omi

10. nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;o gbé mi sókè,o sì jù mí nù.

11. Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,mo sì ń rọ bíi koríko.

12. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran.

13. Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.Àkókò tí o dá tó.

14. Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.

15. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.

16. Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.

17. Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn.

18. Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀,kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA,

19. pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀,láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé;

20. láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn,ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀.

21. Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni,kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu,

22. nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,láti sin OLUWA.

23. Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú.

24. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”

25. Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 102