Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 10:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA,tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

2. Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní;jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ.

3. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀,Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA.

4. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀,kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀.

5. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un.Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ;ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.

6. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú,ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro.

7. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀;ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

8. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa.

9. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba;ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀;ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ.

10. Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba,ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú.

11. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé,OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.”

12. Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i;má sì gbàgbé àwọn tí a nilára.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 10