Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 1:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.

3. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odòtí ń so ní àkókò tí ó yẹ,tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.

4. Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

5. Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6. Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 1