Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 1:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náàtí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.

2. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.

3. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odòtí ń so ní àkókò tí ó yẹ,tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.

4. Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 1