Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 9:4-17 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Mose bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá.

5. Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn.

6. Ṣugbọn àwọn kan wà tí wọn kò lè bá wọn ṣe ọdún náà nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni, wọ́n sì sọ fún wọn pé,

7. “Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?”

8. Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró di ìgbà tí mo bá gbọ́ àṣẹ tí OLUWA yóo pa nípa yín.”

9. OLUWA bá sọ fún Mose pé,

10. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ọ̀kan ninu yín tabi àwọn ọmọ yín bá di aláìmọ́ nítorí pé ó fi ọwọ́ kan òkú; tabi ó wà ní ìrìn àjò, ṣugbọn tí ọkàn rẹ̀ sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá.

11. Anfaani wà fun yín pé kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe é ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Kí ó ṣe é pẹlu burẹdi tí a kò fi ìwúkàrà sí ati ewébẹ̀ kíkorò.

12. Ẹ kò gbọdọ̀ fi àjẹkù kankan sílẹ̀ di ọjọ́ keji, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ ọ̀kankan ninu egungun ẹran tí ẹ bá fi rú ẹbọ náà. Ẹ óo ṣe ọdún Àjọ̀dún Ìrékọjá náà gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.

13. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ́, tí kò lọ sí ìrìn àjò, ṣugbọn tí kò ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ni a ó yọ kúrò láàrin àwọn eniyan mi, nítorí kò mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLUWA ní àkókò rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ níláti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14. “Bí àlejò kan bá wà ní ààrin yín tí ó sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, yóo ṣe é gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Òfin ati ìlànà kan náà ni ó wà fún gbogbo yín, ati onílé ati àlejò.”

15. Ní ọjọ́ tí wọn pa Àgọ́ Àjọ, èyí tí í ṣe Àgọ́ Ẹ̀rí, ìkùukùu bò ó. Ní alẹ́, ìkùukùu náà dàbí ọ̀wọ̀n iná.

16. Ìkùukùu ni lọ́sàn-án, ṣugbọn ní alẹ́, ó dàbí ọ̀wọ̀n iná. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì máa ń rí nígbà gbogbo.

17. Nígbà tí ìkùukùu yìí bá kúrò ní orí Àgọ́ Àjọ àwọn ọmọ Israẹli yóo tú àgọ́ wọn palẹ̀, wọn yóo sì lọ tún un pa níbi tí ìkùukùu náà bá ti dúró.

Ka pipe ipin Nọmba 9