Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 8:19-26 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Mo ti fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti inú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ ati láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn nígbà tí wọn bá súnmọ́ ibi mímọ́.”

20. Mose ati Aaroni ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí wọ́n ṣe.

21. Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

22. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli ṣe fun àwọn ọmọ Lefi, ni wọ́n ṣe.

23. OLUWA sọ fún Mose pé,

24. “Àwọn ọmọ Lefi yóo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ láti ìgbà tí wọ́n bá ti di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn.

25. Nígbà tí wọ́n bá di ẹni aadọta ọdún, iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Àjọ yóo dópin. Wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ níbẹ̀ mọ́,

26. ṣugbọn wọ́n lè máa ran àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́ nípa bíbojú tó wọn; ṣugbọn àwọn gan-an kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe yan iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Lefi fún wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 8