Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 7:79-84 BIBELI MIMỌ (BM)

79. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, pẹlu abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.

80. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;

81. akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

82. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

83. Ahira, ọmọ Enani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia.

84. Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila,

Ka pipe ipin Nọmba 7