Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 7:59-69 BIBELI MIMỌ (BM)

59. Gamalieli ọmọ Pedasuri, kó àwọn akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

60. Ní ọjọ́ kẹsan-an ni Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

61. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọ́n ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

62. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari.

63. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

64. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

65. Abidani ọmọ Gideoni, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

66. Ní ọjọ́ kẹwaa ni Ahieseri ọmọ Amiṣadai, olórí àwọn ẹ̀yà Dani mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

67. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.

68. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari.

69. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

Ka pipe ipin Nọmba 7