Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 7:38-42 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari,

39. akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

40. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

41. Lẹ́yìn náà, Ṣelumieli, ọmọ Suriṣadai tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

42. Ní ọjọ́ kẹfa ni Eliasafu, ọmọ Deueli, olórí àwọn ẹ̀yà Gadi, mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

Ka pipe ipin Nọmba 7