Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 7:34-39 BIBELI MIMỌ (BM)

34. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

35. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ alaafia. Ọrẹ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri nìyí.

36. Ní ọjọ́ karun-un, Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai, olórí ẹ̀yà Simeoni mú ọrẹ tirẹ̀ wa.

37. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.

38. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari,

39. akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

Ka pipe ipin Nọmba 7