Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 6:13-27 BIBELI MIMỌ (BM)

13. “Èyí ni yóo jẹ́ òfin fún Nasiri: Nígbà tí ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé, yóo wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ

14. pẹlu àwọn ọrẹ tí ó fẹ́ fún OLUWA: ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ sísun; abo ọ̀dọ́ aguntan, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ alaafia,

15. pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu.

16. “Alufaa yóo sì kó àwọn nǹkan wọnyi wá siwaju OLUWA, yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun rẹ̀.

17. Yóo fi àgbò náà rú ẹbọ alaafia sí OLUWA pẹlu burẹdi agbọ̀n kan tí kò ní ìwúkàrà ninu. Alufaa yóo fi ohun jíjẹ ati ohun mímu rẹ̀ rúbọ pẹlu.

18. Nasiri náà yóo fá irun orí rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì fi irun náà sinu iná tí ó wà lábẹ́ ẹbọ alaafia.

19. Alufaa yóo fún Nasiri náà ní apá àgbò tí a ti bọ̀ pẹlu burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti fá irun orí rẹ̀.

20. Lẹ́yìn náà ni alufaa yóo fi àwọn ẹbọ náà níwájú OLUWA. Mímọ́ ni wọ́n jẹ́ fún alufaa náà, pẹlu àyà tí a fì ati itan tí wọ́n fi rúbọ. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè máa mu ọtí waini.

21. “Èyí ni òfin Nasiri, ṣugbọn bí Nasiri kan bá ṣe ìlérí ju ẹbọ tí òfin là sílẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ mú ìlérí náà ṣẹ.”

22. OLUWA sọ fún Mose pé

23. kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Báyìí ni ẹ óo máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli.

24. ‘Kí OLUWA bukun yín,kí ó sì pa yín mọ́.

25. Kí OLUWA mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí yín lára,kí ó sì ṣàánú fún yín.

26. Kí OLUWA bojúwò yín,kí ó sì fún yín ní alaafia.’

27. “Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo fi orúkọ mi súre fún àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì bukun wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 6