Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 6:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé,

2. “Nígbà tí ọkunrin tabi obinrin kan bá ṣe ìlérí láti di Nasiri, tí ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA,

3. yóo jáwọ́ kúrò ninu ọtí waini mímu, ati ọtí líle. Kò gbọdọ̀ mu ọtí kíkan tí a fi waini tabi ọtí líle ṣe. Kò gbọdọ̀ mu ọtí èso àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ jẹ èso àjàrà tútù tabi gbígbẹ.

4. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá jẹ́ Nasiri, kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí a fi èso àjàrà ṣe, kì báà jẹ́ kóró tabi èèpo rẹ̀.

5. “Kò gbọdọ̀ gé irun orí rẹ̀ tabi kí ó fá a títí tí ọjọ́ tí ó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo fi pé, kí ó jẹ́ mímọ́, kí ó sì jẹ́ kí ìdì irun orí rẹ̀ máa dàgbà.

6. Ní gbogbo ọjọ́ tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú:

7. kì báà ṣe òkú baba, tabi ti ìyá rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú arakunrin tabi arabinrin rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá kú. Kò gbọdọ̀ ti ipasẹ̀ wọn sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ìyàsímímọ́ Ọlọrun ń bẹ lórí rẹ̀.

8. Yóo jẹ́ mímọ́ fún OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.

9. “Bí ẹnìkan bá kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lójijì, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ orí rẹ̀ di aláìmọ́; yóo dúró fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje tí í ṣe ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, yóo fá irun orí rẹ̀.

10. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

11. Alufaa yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi ikeji rú ẹbọ sísun láti ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa fífi ara kan òkú; yóo sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà.

12. Lẹ́yìn náà ni ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a kì yóo ka àwọn ọjọ́ tí ó ti lò ṣáájú nítorí pé ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti bàjẹ́ nítorí pé ó fi ara kan òkú. Yóo sì mú ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan tọ alufaa wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

13. “Èyí ni yóo jẹ́ òfin fún Nasiri: Nígbà tí ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé, yóo wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ

14. pẹlu àwọn ọrẹ tí ó fẹ́ fún OLUWA: ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ sísun; abo ọ̀dọ́ aguntan, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ alaafia,

15. pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu.

16. “Alufaa yóo sì kó àwọn nǹkan wọnyi wá siwaju OLUWA, yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun rẹ̀.

17. Yóo fi àgbò náà rú ẹbọ alaafia sí OLUWA pẹlu burẹdi agbọ̀n kan tí kò ní ìwúkàrà ninu. Alufaa yóo fi ohun jíjẹ ati ohun mímu rẹ̀ rúbọ pẹlu.

Ka pipe ipin Nọmba 6