Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 5:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Nígbà náà ni alufaa yóo mú kí obinrin náà búra, yóo wí fún un pé, ‘Bí ọkunrin kankan kò bá bá ọ lòpọ̀, tí o kò sì ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ, ègún inú omi kíkorò yìí kò ní ṣe ọ́ ní ibi.

20. Ṣugbọn bí o bá tí ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ (níwọ̀n ìgbà tí o wà ní ilé rẹ̀), tí o sì ti sọ ara rẹ di aláìmọ́ nípa pé ọkunrin mìíràn bá ọ lòpọ̀,

21. kí OLUWA sọ ọ́ di ẹni ègún ati ẹni ìfibú láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí OLUWA mú kí abẹ́ rẹ rà, kí ó sì mú kí ara rẹ wú.

22. Kí omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí wọ inú rẹ, kí ó mú kí inú rẹ wú, kí ó sì mú kí abẹ́ rẹ rà.’“Obinrin náà yóo sì dáhùn pé, ‘Amin, Amin.’

23. “Lẹ́yìn èyí, kí alufaa kọ ègún yìí sinu ìwé, kí ó sì fọ̀ ọ́ sinu abọ́ omi kíkorò náà.

24. Kí obinrin náà mu ún, omi náà yóo sì mú kí ó ní ìrora.

25. Nígbà náà ni alufaa yóo gba ẹbọ ohun jíjẹ ti owú náà lọ́wọ́ obinrin náà yóo sì fì í níwájú OLUWA, lẹ́yìn èyí, yóo gbé e sórí pẹpẹ.

26. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà fún ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ; lẹ́yìn náà, yóo ní kí obinrin náà mu omi yìí.

27. Bí ó bá jẹ́ pé obinrin náà ti ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ọkunrin mìíràn bá ti bá a lòpọ̀, omi náà yóo korò ninu rẹ̀, yóo sì mú kí inú rẹ̀ wú, kí abẹ́ rẹ̀ sì rà. Yóo sì fi bẹ́ẹ̀ di ẹni ègún láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

28. Ṣugbọn bí obinrin náà kò bá tí ì ba ara rẹ̀ jẹ́, ègún náà kò ní lágbára lórí rẹ̀, yóo sì lóyún.

29. “Èyí ni ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe nígbà tí obinrin bá ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ọkunrin mìíràn bá a lòpọ̀;

30. tabi nígbà tí ọkunrin kan bá ń ṣiyèméjì nípa ìdúró iyawo rẹ̀, ọkunrin náà yóo mú iyawo rẹ̀ wá siwaju OLÚWA, alufaa yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ yìí.

31. Nígbà náà ni ọkunrin náà yóo bọ́ ninu ẹ̀bi, ṣugbọn obinrin náà yóo forí ru ẹ̀bi àìdára tí ó ṣe.”

Ka pipe ipin Nọmba 5