Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 5:14-19 BIBELI MIMỌ (BM)

14. tabi bí ẹnìkan bá ń jowú tí ó sì rò pé ọkunrin kan ń bá iyawo òun lòpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀,

15. kí olúwarẹ̀ mú iyawo rẹ̀ wá sọ́dọ̀ alufaa, kí ó sì mú ọrẹ rẹ̀ tíí ṣe ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun ọkà baali wá fún alufaa. Kò gbọdọ̀ da òróró sí orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ fi turari sinu rẹ̀, nítorí pé ẹbọ owú ni, tí a rú láti múni ranti àìdára tí eniyan ṣe.

16. “Alufaa yóo sì mú kí obinrin náà dúró níwájú pẹpẹ OLUWA,

17. yóo da omi mímọ́ sinu àwo kan, yóo bù lára erùpẹ̀ ilẹ̀ Àgọ́ Àjọ sinu omi náà.

18. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo mú obinrin náà wá siwaju OLUWA, yóo tú irun orí obinrin náà, yóo sì gbé ẹbọ ìrántí lé e lọ́wọ́, tíí ṣe ẹbọ ohun jíjẹ ti owú. Àwo omi kíkorò, tí ó ń mú ègún wá yóo sì wà lọ́wọ́ alufaa.

19. Nígbà náà ni alufaa yóo mú kí obinrin náà búra, yóo wí fún un pé, ‘Bí ọkunrin kankan kò bá bá ọ lòpọ̀, tí o kò sì ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ, ègún inú omi kíkorò yìí kò ní ṣe ọ́ ní ibi.

Ka pipe ipin Nọmba 5