Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 4:34-46 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli ka àwọn ọmọ Kohati ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

35. Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé ẹni aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

36. Iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹrinla ó dín aadọta (2,750).

37. Iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Kohati nìyí, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.

38. Iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn,

39. láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ

40. jẹ́ ẹgbẹtala ó lé ọgbọ̀n (2,630).

41. Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Geriṣoni tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.

42. Àwọn tí a kà ninu àwọn ọmọ Merari, ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn,

43. láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ

44. jẹ́ ẹgbẹrindinlogun (3,200).

45. Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Merari gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.

46. Gbogbo àwọn tí Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli kà ninu àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn,

Ka pipe ipin Nọmba 4