Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 36:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

10. Àwọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA fún Mose;

11. Mahila, Tirisa, Hogila, Milika ati Noa fẹ́ ọkọ láàrin àwọn arakunrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.

12. Wọ́n fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, ilẹ̀-ìní wọn sì dúró ninu ẹ̀yà baba wọn.

13. Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA ti pa láṣẹ fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ní òdìkejì Jẹriko.

Ka pipe ipin Nọmba 36