Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 36:5-8 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Mose bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí fún un, pé, “Ohun tí ẹ̀yà Manase sọ dára,

6. nítorí náà OLUWA wí pé àwọn ọmọbinrin Selofehadi ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wù wọ́n, ṣugbọn ó gbọdọ̀ jẹ́ láti inú ẹ̀yà wọn.

7. Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

8. Obinrin tí ó bá ní ilẹ̀-ìní gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà rẹ̀, kí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli lè máa jogún ilẹ̀ ìní baba rẹ̀.”

Ka pipe ipin Nọmba 36