Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 35:25-34 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Kí ìjọ eniyan gba ẹni tí ó paniyan náà lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí wọ́n mú un pada lọ sí ìlú ààbò rẹ̀. Níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí tí olórí alufaa tí a fi òróró yàn yóo fi kú.

26. Ṣugbọn bí apànìyàn náà bá rékọjá odi ìlú ààbò rẹ̀,

27. tí arakunrin ẹni tí ó pa bá rí i tí ó sì pa á, olùgbẹ̀san náà kì yóo ní ẹ̀bi;

28. nítorí pé apànìyàn náà gbọdọ̀ dúró ní ìlú ààbò rẹ̀ títí tí olórí alufaa yóo fi kú, lẹ́yìn náà, ó lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

29. Èyí yóo jẹ́ ìlànà ati òfin fun yín láti ìrandíran yín níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

30. “Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn.

31. Kí ẹ má ṣe gba owó ìtanràn lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa òun náà.

32. Bí apànìyàn kan bá sá lọ sí ìlú ààbò, ẹ kò gbọdọ̀ gba owó ìtanràn lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó baà lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ṣáájú ikú olórí alufaa.

33. Bí ẹ bá ṣe èyí, ẹ óo sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́ nítorí pé ìpànìyàn a máa sọ ilẹ̀ di àìmọ́. Ikú apànìyàn nìkan ni ó sì lè ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilẹ̀ tí ó ti di àìmọ́ nípa ìpànìyàn.

34. Ẹ má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, àní, ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli láàrin àwọn tí èmi OLUWA ń gbé.”

Ka pipe ipin Nọmba 35