17. “Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín.
18. Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”
19. Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune.
20. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu.
21. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, a yan Elidadi ọmọ Kisiloni.
22. Láti inú ẹ̀yà Dani, a yan Buki ọmọ Jogili.
23. Láti inú ẹ̀yà Manase, a yan Hanieli ọmọ Efodu.