Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 34:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”

13. Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù.

14. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

15. ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.”

16. OLUWA sọ fún Mose pé,

17. “Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín.

18. Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”

19. Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune.

20. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu.

Ka pipe ipin Nọmba 34