Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 33:41-56 BIBELI MIMỌ (BM)

41. Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona.

42. Wọ́n kúrò ní Salimona wọ́n lọ sí Punoni.

43. Láti Punoni wọ́n lọ sí Obotu.

44. Láti Obotu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu ní agbègbè Moabu.

45. Láti Iyimu wọ́n lọ sí Diboni Gadi.

46. Láti Diboni Gadi wọ́n lọ sí Alimoni Dibilataimu.

47. Láti Alimoni Dibilataimu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu níwájú Nebo.

48. Láti Òkè Abarimu wọ́n lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko.

49. Wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ẹ̀bá odò Jọdani láti Beti Jeṣimotu títí dé Abeli Ṣitimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu.

50. OLUWA sọ fún Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko pé

51. kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá ré odò Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani,

52. ẹ gbọdọ̀ lé gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà kúrò. Ẹ run gbogbo àwọn oriṣa tí wọ́n fi òkúta ati irin ṣe ati gbogbo ilé oriṣa wọn.

53. Kí ẹ gba ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí pé mo ti fun yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní yín.

54. Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà.

55. Ṣugbọn bí ẹ kò bá lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò, àwọn tí ó bá kù yóo di ẹ̀gún ní ojú yín ati ẹ̀gún ní ìhà yín, wọn yóo sì máa yọ yín lẹ́nu lórí ilẹ̀ náà.

56. Bí ẹ kò bá lé gbogbo wọn jáde, ohun tí mo ti pinnu láti ṣe sí wọn, ẹ̀yin ni n óo ṣe é sí.”

Ka pipe ipin Nọmba 33