Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 33:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ibi tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí ninu ìrìn àjò wọn láti ìgbà tí wọn ti kúrò ní Ijipti lábẹ́ àṣẹ Mose ati Aaroni nìwọ̀nyí:

2. (Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.)

3. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti,

4. tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ.

5. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Sukotu.

6. Wọ́n kúrò ní Sukotu, wọ́n lọ pàgọ́ sí Etamu tí ó wà létí aṣálẹ̀.

7. Láti ibẹ̀ wọ́n pada sẹ́yìn lọ sí Pi Hahirotu tí ó wà níwájú Baali Sefoni, wọ́n pàgọ́ siwaju Migidoli.

8. Wọ́n kúrò níwájú Pi Hahirotu, wọ́n la ààrin òkun kọjá lọ sinu aṣálẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ mẹta ninu aṣálẹ̀ Etamu, wọ́n pàgọ́ sí Mara.

9. Wọ́n kúrò ní Mara, wọ́n lọ pàgọ́ sí Elimu níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà.

10. Wọ́n kúrò ní Elimu, wọ́n lọ pàgọ́ sí etí Òkun Pupa.

11. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ pàgọ́ sí aṣálẹ̀ Sini.

12. Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika.

Ka pipe ipin Nọmba 33