Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 32:4-16 BIBELI MIMỌ (BM)

4. tí OLUWA ti ran àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára fún ẹran ọ̀sìn, àwa iranṣẹ yín sì ní ẹran ọ̀sìn pupọ.

5. Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”

6. Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni?

7. Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn?

8. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi Banea láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà.

9. Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn.

10. Nítorí náà ni ibinu Ọlọrun ṣe ru sí wọn nígbà náà. Ó sì búra pé,

11. ‘Ọ̀kan ninu àwọn tí ó ti ilẹ̀ Ijipti wá, láti ẹni ogún ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣèlérí fún Abrahamu, fún Isaaki ati fún Jakọbu, nítorí pé wọn kò fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.’

12. Àfi Kalebu ọmọ Jefune, ọmọ Kenisi ati Joṣua ọmọ Nuni, nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.

13. Ibinu OLUWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì mú wọn rìn kiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún títí gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe burúkú níwájú OLUWA fi kú tán.

14. Nisinsinyii, ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín láti mú kí inú bí OLUWA gidigidi sí Israẹli.

15. Bí ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pada lẹ́yìn OLUWA, yóo kọ àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. A jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ fa ìparun wọn.”

16. Wọ́n dá Mose lóhùn pé, “A óo kọ́ ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa níhìn-ín ati ìlú olódi fún àwọn ọmọ wa.

Ka pipe ipin Nọmba 32