Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 32:24-42 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Ẹ lọ kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín ati ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ ṣèlérí.”

25. Àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi sì dá Mose lóhùn, wọ́n ní,

26. “Àwọn ọmọ wa, àwọn aya wa, àwọn mààlúù wa ati aguntan wa yóo wà ní àwọn ìlú Gileadi,

27. ṣugbọn a ti ṣetán láti lọ sí ojú ogun nípa àṣẹ OLUWA. A óo ré odò Jọdani kọjá láti jagun gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.”

28. Mose bá pàṣẹ fún Eleasari alufaa, ati fún Joṣua ọmọ Nuni ati fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli nípa wọn, ó ní,

29. “Bí àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi bá bá yín ré odò Jọdani kọjá láti jagun níwájú OLUWA, bí wọ́n bá sì ràn yín lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà, ẹ óo fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

30. Ṣugbọn bí wọn kò bá bá yín ré odò Jọdani kọjá, tí wọn kò sì lọ sí ojú ogun pẹlu yín, wọn óo gba ìpín ilẹ̀ ìní tiwọn ní Kenaani bíi àwọn ọmọ Israẹli yòókù.”

31. Àwọn ọmọ Gadi ati àwọn ọmọ Reubẹni dáhùn, wọ́n ní, “A óo ṣe ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ.

32. Nípa àṣẹ rẹ̀ ni a óo ré odò Jọdani kọjá, a óo lọ jagun ní ilẹ̀ Kenaani, kí ilẹ̀ ìhà ìlà oòrùn Jọdani lè jẹ́ tiwa.”

33. Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu.

34. Àwọn ọmọ Gadi sì tún àwọn ìlú olódi wọnyi kọ́: Diboni, Atarotu ati Aroeri,

35. ati Atirotu Ṣofani, Jaseri, Jogibeha,

36. ati Beti Nimra, Beti Harani, àwọn ìlú olódi ati ilé fún àwọn aguntan.

37. Àwọn ọmọ Reubẹni tún àwọn ìlú wọnyi kọ́: Heṣiboni, Eleale, Kiriataimu,

38. Nebo, Baali Meoni (wọ́n yí orúkọ ìlú yìí pada) ati Sibima. Wọ́n sì fún àwọn ìlú tí wọn tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.

39. Àwọn ọmọ Makiri tíí ṣe ẹ̀yà Manase gbógun ti àwọn ará Amori tí ó wà ní Gileadi, wọ́n lé wọn jáde, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

40. Nítorí náà Mose fi ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Makiri láti inú ẹ̀yà Manase, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

41. Jairi ọmọ Manase gbógun ti àwọn ìlú kan, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ wọn ní Hafoti Jairi.

42. Noba gbógun ti Kenati ati àwọn ìletò rẹ̀, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Noba tíí ṣe orúkọ ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 32