Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 32:17-30 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu.

18. A kò ní pada sí ilẹ̀ wa títí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ní ilẹ̀ ìní tirẹ̀.

19. A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.”

20. Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí nǹkan tí ẹ sọ yìí bá ti ọkàn yín wá, tí ẹ bá di ihamọra ogun yín níwájú OLUWA,

21. tí àwọn ọmọ ogun yín sì ṣetán láti ré odò Jọdani kọjá ní àṣẹ OLUWA láti gbógun ti àwọn ọ̀tá wa títí OLUWA yóo fi pa wọ́n run,

22. tí yóo sì gba ilẹ̀ náà, lẹ́yìn náà, ẹ lè pada nítorí pé ẹ ti ṣe ẹ̀tọ́ yín sí OLUWA ati sí àwọn arakunrin yín. Ilẹ̀ yìí yóo sì máa jẹ́ ìní yín pẹlu àṣẹ OLUWA.

23. Ṣugbọn bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ jẹ́ kí ó da yín lójú pé ẹ kò ní lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín.

24. Ẹ lọ kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín ati ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ ṣèlérí.”

25. Àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi sì dá Mose lóhùn, wọ́n ní,

26. “Àwọn ọmọ wa, àwọn aya wa, àwọn mààlúù wa ati aguntan wa yóo wà ní àwọn ìlú Gileadi,

27. ṣugbọn a ti ṣetán láti lọ sí ojú ogun nípa àṣẹ OLUWA. A óo ré odò Jọdani kọjá láti jagun gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.”

28. Mose bá pàṣẹ fún Eleasari alufaa, ati fún Joṣua ọmọ Nuni ati fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli nípa wọn, ó ní,

29. “Bí àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi bá bá yín ré odò Jọdani kọjá láti jagun níwájú OLUWA, bí wọ́n bá sì ràn yín lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà, ẹ óo fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

30. Ṣugbọn bí wọn kò bá bá yín ré odò Jọdani kọjá, tí wọn kò sì lọ sí ojú ogun pẹlu yín, wọn óo gba ìpín ilẹ̀ ìní tiwọn ní Kenaani bíi àwọn ọmọ Israẹli yòókù.”

Ka pipe ipin Nọmba 32