Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 32:12-23 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àfi Kalebu ọmọ Jefune, ọmọ Kenisi ati Joṣua ọmọ Nuni, nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.

13. Ibinu OLUWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì mú wọn rìn kiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún títí gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe burúkú níwájú OLUWA fi kú tán.

14. Nisinsinyii, ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín láti mú kí inú bí OLUWA gidigidi sí Israẹli.

15. Bí ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pada lẹ́yìn OLUWA, yóo kọ àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. A jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ fa ìparun wọn.”

16. Wọ́n dá Mose lóhùn pé, “A óo kọ́ ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa níhìn-ín ati ìlú olódi fún àwọn ọmọ wa.

17. Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu.

18. A kò ní pada sí ilẹ̀ wa títí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ní ilẹ̀ ìní tirẹ̀.

19. A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.”

20. Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí nǹkan tí ẹ sọ yìí bá ti ọkàn yín wá, tí ẹ bá di ihamọra ogun yín níwájú OLUWA,

21. tí àwọn ọmọ ogun yín sì ṣetán láti ré odò Jọdani kọjá ní àṣẹ OLUWA láti gbógun ti àwọn ọ̀tá wa títí OLUWA yóo fi pa wọ́n run,

22. tí yóo sì gba ilẹ̀ náà, lẹ́yìn náà, ẹ lè pada nítorí pé ẹ ti ṣe ẹ̀tọ́ yín sí OLUWA ati sí àwọn arakunrin yín. Ilẹ̀ yìí yóo sì máa jẹ́ ìní yín pẹlu àṣẹ OLUWA.

23. Ṣugbọn bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ jẹ́ kí ó da yín lójú pé ẹ kò ní lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín.

Ka pipe ipin Nọmba 32