Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 32:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn pupọ, rí ilẹ̀ Jaseri ati ilẹ̀ Gileadi pé ibẹ̀ dára fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn,

2. wọ́n wá siwaju Mose, ati Eleasari ati àwọn olórí àwọn eniyan, wọ́n ní,

3. “Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni,

4. tí OLUWA ti ran àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára fún ẹran ọ̀sìn, àwa iranṣẹ yín sì ní ẹran ọ̀sìn pupọ.

5. Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”

6. Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni?

7. Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn?

8. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi Banea láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà.

9. Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn.

Ka pipe ipin Nọmba 32