Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 31:46-54 BIBELI MIMỌ (BM)

46. Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaa mẹjọ (16,000).

47. Ninu wọn, Mose mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu araadọta ninu àwọn eniyan ati ẹranko, ó sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA, bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

48. Lẹ́yìn náà ni àwọn olórí ogun àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un tọ Mose wá, wọ́n wí pé,

49. “A ti ka àwọn ọmọ ogun tí ó wà lábẹ́ wa, kò sí ẹni tí ó kú sójú ogun.

50. Nítorí náà a mú ọrẹ ẹbọ: ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, ẹ̀wọ̀n, ẹ̀gbà ọwọ́, òrùka, yẹtí, ati ìlẹ̀kẹ̀ wá fún OLUWA lára ìkógun wa, láti fi ṣe ẹbọ ètùtù fún wa níwájú OLUWA.”

51. Mose ati Eleasari gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mìíràn náà lọ́wọ́ wọn.

52. Ìwọ̀n gbogbo ọrẹ ẹbọ tí àwọn olórí ogun náà mú wá jẹ́ ẹgbaajọ ó lé ẹẹdẹgbẹrin ó lé aadọta (16,750) ṣekeli.

53. Àwọn ọmọ ogun tí wọn kì í ṣe olórí ogun ti kó ìkógun tiwọn.

54. Mose ati Eleasari kó wúrà náà lọ sinu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú OLUWA.

Ka pipe ipin Nọmba 31