Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 31:27-33 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Pín gbogbo ìkógun náà sí meji, kí apákan jẹ́ ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, kí apá keji sì jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli yòókù.

28. Yọ apákan sílẹ̀ fún OLUWA lára ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, ninu ẹẹdẹgbẹta tí o bá kà ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn, ọ̀kan jẹ́ ti OLUWA.

29. Yọ ọ́ lára ìkógun wọn kí o sì kó wọn fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA.

30. Lára ìdajì tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, mú ẹyọ kan ninu araadọta ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn; kí o sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA.”

31. Mose ati Eleasari sì ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn.

32. Ìkógun tí ó kù ninu àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó bọ̀ láti ojú ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹrinlelọgbọn ó dín ẹgbẹẹdọgbọn (675,000) aguntan.

33. Ẹgbaa mẹrindinlogoji (72,000) mààlúù.

Ka pipe ipin Nọmba 31