Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 30:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. ó gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ rẹ̀, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí i nígbà tí ó gbọ́.

12. Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, obinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

13. Ọkọ rẹ̀ ní àṣẹ láti gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tabi kí ó kọ̀ fún un láti san án.

14. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ kò bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́, ó níláti san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò lòdì sí i.

15. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà lẹ́yìn èyí, ọkọ náà ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ obinrin náà nítorí pé kò jẹ́ kí ó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

16. Bẹ́ẹ̀ ni ìlànà tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose láàrin ọkọ ati aya ati láàrin baba ati ọmọ rẹ̀ obinrin, tí ń gbé ninu ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 30