Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 3:7-23 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.

8. Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.

9. Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

10. Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.”

11. OLUWA sọ fún Mose pé,

12. “Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi,

13. nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.”

14. OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai, ó ní,

15. “Ka iye àwọn ọmọkunrin Lefi gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ oṣù kan lọ sókè.”

16. Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

17. Lefi ní ọmọkunrin mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari, wọ́n sì jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn.

18. Orúkọ àwọn ọmọ Geriṣoni ni Libini ati Ṣimei.

19. Orúkọ àwọn ọmọ Kohati ni Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli.

20. Orúkọ àwọn ọmọ Merari ni Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

21. Geriṣoni ni baba ńlá àwọn ọmọ Libini ati àwọn ọmọ Ṣimei.

22. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn, láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó dín ẹẹdẹgbẹta (7,500).

23. Àwọn ọmọ Geriṣoni yóo pàgọ́ tiwọn sẹ́yìn Àgọ́ Àjọ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

Ka pipe ipin Nọmba 3