Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 3:39-51 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000).

40. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí lọkunrin láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti ọmọ oṣù kan sókè, kí o sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀.

41. Gba àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò awọn àkọ́bí ní Israẹli, sì gba àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, dípò àwọn àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni OLUWA.”

42. Mose bá ka gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

43. Gbogbo àkọ́bí ọkunrin, gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn, lati ọmọ oṣù kan lọ sókè ní iye wọn, lápapọ̀, wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba ati mẹtalelaadọrin (22,273).

44. OLUWA sọ fún Mose pé,

45. “Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli, ati ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn wọn. Àwọn ọmọ Lefi yóo sì jẹ́ tèmi. Èmi ni OLUWA.

46. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àkọ́bí Israẹli fi igba ó lé mẹtalelaadọrin (273) pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ, wọ́n níláti rà wọ́n pada.

47. Kí o gba ṣekeli marun-un-marun-un lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́.

48. Kí o sì kó owó náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀.”

49. Mose gba owó ìràpadà náà lórí àwọn tí iye àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli fi pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ.

50. Owó tí ó gbà jẹ́ egbeje ìwọ̀n ṣekeli fadaka ó dín marundinlogoji (1,365), gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́.

51. Mose fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ní owó ìràpadà náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọmba 3