Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 3:34-42 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaata lé igba (6,200).

35. Surieli ọmọ Abihaili ni yóo jẹ́ olórí wọn. Kí wọ́n pàgọ́ tiwọn sí ìhà àríwá Àgọ́ Àjọ.

36. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn igi àkànpọ̀ ibi mímọ́, ati àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ wọn;

37. ati gbogbo òpó àgbàlá yíká, pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, èèkàn wọn, ati okùn wọn.

38. Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.

39. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000).

40. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí lọkunrin láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti ọmọ oṣù kan sókè, kí o sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀.

41. Gba àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò awọn àkọ́bí ní Israẹli, sì gba àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, dípò àwọn àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni OLUWA.”

42. Mose bá ka gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọmba 3